Okwu nke Ụbọchị

Okwu nke Ụbọchị
October 2, 2026

Ọlọ́run Fi ise le Mósè lowo 53-0508

Nísinsìnyí, mofẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí o pani lerin gaan, jẹ́ kí a wo bí Mose ṣe ń sọ̀kalẹ̀ latórí òkè níbí báyìí. Òwúrọ̀ daradara kan, oòrùn ń yọ, àwọn ẹyẹ ń korin, bi ọkùnrin àgbàlagbà kan se de niyen, ẹni ọgọ́rin ọdún, irugbon ti boo, irun funfun sì ńwo tọ́ lẹ́yìn, ó ń fa ìbakasie kékeré kan lowo to gbe ìyàwó pẹ̀lú ọmọ Mose kékeré sehin, o mu ọ̀pá wiwo kan dani Ó ń lọ.

“Níbo lon ń lọ, Mósè?”

“Mo nlọ sí Íjíbítì láti gba ìjọba!” ọkùnrin kan ṣoṣo to n kogun ja Ejipiti. Se ni Íjíbítì dàbí lílọ sí Rọ́síà láti gba ìjọba nibe.

Àwọn nkàn ogun jijà tí ó dára jùlọ l’ayé wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún un pé, “Èmi yóò rán ọ síbe láti gbajọba.”

“Ó dárao, Mose, se pé ìwọ yóò gba ìjọba?”

“Dájúdájú.”

“Kí ló dé? Nípasẹ̀ rẹ…”

“Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run sọ bẹ́ẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni.

Ẹ sọ pé, “Ṣé ofe ló gbà?”

Mose dahun” Dájúdájú, a ó gbà ijoba nisisinyi. Lobatan. Ọlọ́run sọ bẹ́ẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni. Níwọ́n ìgbà tí Ọlọ́run ti sọ bẹ́ẹ̀, àmín. Ìyẹn— Oro buse.

Bí Ọlọ́run bá sọ bẹ́ẹ̀, ẹ lè ṣe é. Abi bee ko? Ti oba ribe, e jẹ́ kí a gbà ijoba nísinsìnyí, kí a sì sọ fún satani pé kò ní ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú wa mọ́. Gbogbo aláìsàn yóò rí ìwòsàn; gbogbo ojú afọ́jú yóò la; gbogbo adití yóò gbọ́ran; gbogbo ahọ́n to yadi yóò sọ̀rọ̀; gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ṣubú niwaju pèpé, wọn yóò sì fi ọkàn wọn fún Kristi. A ó gbàjoba. Seeri? Ọlọ́run tifi fún wa. Ẹ tesiwaju láti gbaa.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́

Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
Lúùkù 10:19

An Independent Church of the WORD,