26-1018 Afinimọna Kan

Eyin Ilé-Agbára owọn,

Ọlọ́run ṣèlérí láti rán afinimọna kan sí Ìyàwó Rẹ̀ ní ígbà ìkẹyìn yí kí Ó lè fi Ara Rẹ̀ hàn nínú ara, gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe nígbà tí Ó wá sí ayé nínú Ọmọ Rẹ̀, Jesu Kristi. Ó sọ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pé Òun yóò rán wòlíì Elíjàh, ẹni tí yóò jẹ́ Ọmọ-Ènìyàn tí ń fi Ara Rẹ̀ hàn nínú ara ènìyàn; nítorí pé Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó ṣì ku láti sọ àti latí kọ́ wa.

Kì yóò sọ oro ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ: yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín. Nítorí pé, òun yóò máa yìn Mí lógo: nítorí tí yóò gbo latenu mi, yóò sì máa fi han yín.

Ó rán William Marrion Branham láti mú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ, àti láti kọ́ eni kookan wa gege bi Ìri ati aworan Jesu Kristi; gege bi ọkùnrin pípé tí ó lè ṣẹ́gun gbogbo ọ̀tá, tí ó sì maa jẹ́ ilé-agbára fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti gbé nínú rẹ̀.

Ọlọ́run kò tíì kùnà ri láti máa rán afinimọna sí àwọn ènìyàn Rẹ̀. Ṣùgbọ́n láti jẹ́ Ìyàwó Rẹ̀, o ní láti gba afinimọna náà. O ní láti gbàa gbọ́. O ní láti tọ̀ ọ̀nà tí ó fi han o, ai jebe ìwọ yóò sọnù. Botiwu ki erò okan wa dabi pe o dara to, tàbí ibaa je ohun asán, Olorun ko funwa ni áṣẹ láti pín ọ́ro naa; afinimọna ni ẹni kan ṣoṣo ti a fi ran.

Ole sọ wipé, Arákùnrin Joseph, Ẹ̀mí Mímọ́ ni láti tọ́ wa, kì í ṣe Arákùnrin Branham.

Emi mimo ni Àwọn Ọ̀rọ̀ to so, kì í sì ṣe Arákùnrin Branham; ṣùgbọ́n òun ni ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fi Ẹ̀mí Mímọ́ hàn nínú rẹ̀, àti láti jẹ́ afinimọna wa ni ayé yi.

Àti nísinsìnyí Ọlọ́run ti máa ń rán àwọn afinimọna Rẹ̀, Kò sí ìgbà tí Olorun kò ní afinimọna, láti ìgbà dé ìgbà. Ọlọ́run ti máa ní ẹnìkan tí ó ń ṣojú Rẹ̀ nínu ayé yìí, ní gbogbo ìgbà.

A gbọ́dọ̀ mọ ẹni tí afinimọna ayé náà jẹ́ tí ń ṣojú Rẹ̀ níbí lórí ile ayé; níbẹ̀ ni Ìfihàn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ gbe wa.

A mọ̀ pé Ẹ̀mí Mímọ́ ni Atọ́nà to ga julo tí Baba rán láti darí Rẹ̀, ṣùgbọ́n níbí yi, Ọlọ́run sọ pé Òun máa rán ọkùnrin kan láti jẹ́ afinimọna láti ṣojú Ara Rẹ̀ àti lati darí Ìyàwó Rẹ̀.

Afinimọna wa sọ fún wa pé Koniliu jẹ́ eni ńlá àti ijóyè kan tí ó kọ́ àwọn ile ìjọsin fun awon eniyan. Ó n se itọrẹ àánú, ó sì ń gbàdúrà lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ dé, Koniliu nílò Afinimọna.

Ọlọ́run rán Ẹ̀mí Mímọ́ sí i. Ó ráan nínú ènìyàn, iyen nipase Peteru, Bibeli wipe “Nígbà tí Peteru ń sọ àwọn Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ẹ̀mí Mímọ́ sokale, o bale won” Ọlọ́run lo Afinimọna nípasẹ̀ Peteru. Ó lò Ó, nítorí pé Ó tọ́ Koniliu sí ọ̀nà tòótọ́.

Nígbà tí Peteru ń sọ̀rọ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bale wọn. Peteru si wipe,

“Enikeni haa lè ṣe ìdènà omi, kí a má baptisi wọ́n bi?” Wò ó, Afinimọna lo ń sọ̀rọ̀ níbẹ̀, kì í ṣe Peteru.

A kì í darí wa latodo eniyan; a ń darí wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni, ẸNI TÍ Ń SỌ̀RỌ̀ NÍPASẸ̀ ỌKÙNRIN TÍ ỌLỌ́RUN YÀN LÁTI JẸ́ AFINIMỌNA WA NINU AYÉ YI.

Ẹ̀mí Mímọ́ ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Angeli afinimọna Rẹ̀ yóò máa sọ kiki Ọ̀rọ̀ re.

Ó sọ fún wa pe, “Mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun láti ba yin sọ. sugbon kò lè yé yin nísinsìnyí, ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dé, Òun yóò tọ́ yín ”

A dari Johanu nígbà tí ó kọ iwe Ìfihàn. A darí re nípasẹ̀ Afinimọna. A tun darí re nípasẹ̀ Afinimọna láti sọ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ ọ̀rọ̀ kan kúrò nínú Rẹ̀, tàbí kí ó fi ọ̀rọ̀ kan kún Un, òun náà ni a ó yọ, ipá rẹ̀, kúrò nínú Ìwé Ìyè.”

Ẹ̀mí Mímọ́ tún darí Arákùnrin Branham láti sọ pé a gbọ́dọ̀ sọ ohun tí ó wà lórí àwọn fonran nìkan; kí a má fi kún tàbí yọ kúrò. Ó sì ti pèsè ọ̀nà kan tí a lè ṣe gangan ohun tí ó kọ́ wa pé a gbọ́dọ̀ ṣe, Tẹ̀ Play.

Nísinsìnyí, báwo ni ìwọ yóò ṣe fi nkàn miran rọ́pò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí o sì tún n sọ pé Ẹ̀mí Mímọ́ ń darí re?

A ń darí wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ẹni tí ó ti fún wa ní Ìfihàn ẹni tí Ó jẹ́, ẹni tí Ó rán gẹ́gẹ́ bí afinimọna wa ninu ayé yi láti pe Ìyàwó Rẹ̀ jáde, àti nísinsìnyí okuta asibori náà: Ìfihàn ẹni tí a jẹ́. Ó kọjá ohun ti ènìyàn lee ṣàlàyé re.

Wò ohun tí Ó ti ṣe fún wa, nínú àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó kọjá yìí. Ó kọ́ wa bí a ṣe lè ṣẹ́gun gbogbo ọ̀tá tí ó bá wa síwájú wa; bí a ṣe lè fa Idà ÌGBÀGBỌ́ wa yo láti pa á. A kò ní ohun kankan láti bẹ̀rù. Kò sí ohun tí ó lè dúró níwájú wa.

Bí Ó ṣe pa Oúnjẹ Naa mọ́ fún Ìyàwó Rẹ̀ láti jẹ. Bí ìránṣẹ́ Rẹ̀ tile wà lòkèerè gaan, a sì ní Afinimọna kan tí ayé kò mọ̀ nkankan nípa rẹ̀; ṣùgbọ́n sí Ìyàwó Rẹ̀, Ó jẹ́ Oúnjẹ Ẹ̀mí ní Àkókò Tó Tọ́, Manna Ìkọ̀kọ̀ tí a ń jẹ lójoojúmọ́.

Ó ti kọ́ wa gege bí ìri àwọn ọkùnrin pípé kí Ó lè maa gbé nínú ẹni kọ̀ọ̀kan wa. Ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀ sí wa, Ó sì fara Rẹ̀ hàn nínú ara, gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe ní egberun odun meji sẹ́yìn, láti jẹ́ Afinimọna wa, o ń gbé osi n sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ afinimọna Rẹ̀ lori ile aye.

Mo pe ẹni kọ̀ọ̀kan yín láti wá gbọ́ “Honk-honk, honk-honk!” Rẹ̀, níbi tí Ìyàwó yóò tọ́ tààrà sí Honk náà. Òun Naa yóò, “Honk-honk, honk-honk!” ìrohìn ayọ̀ ńlá yóò sì wà káàkiri gbogbo ayé. Kí ló dé? Ìyàwó mọ Ohùn Afinimọna re.

Bí o kò bá fẹ́ sọnù, wá gbọ́ Afinimọna wa bí Ó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ afinimọna wa layé tí a yàn ní ọjọ́ Ìsìnní yìí ní agogo mejila ọ̀sán, àkókò Jeffersonville.

Arákùnrin Joseph Branham

Akori Ìwaasu: 62-1014E — “Afinimọna Kan”

Ìwé Mímọ́:
Márkù 16:15-18
Johánù 1:1 / 16:7-15
Ìṣe Àwọn Aposteli 2:38
Efesu 4:11-13 / 4:30
Heberu 4:12
2 Peteru 1:21
Éksódù 13:21